HYMN 850

D.S.M (FE 891) 
Tune: Olorun Serafu



1.  EGBE awon angeli 

     Egbe ogun orun

     Egbe awon Aposteli 
 
     Awon Eni-Mimo 

     Gbogbo won loke orun 

     Nyin O tosan-toru 

     Olorun Metalokan wa

     Oga-Ogo julo.


2.  Legbegbe l’awa pejo 

     Niwaju Re, Baba 

     Lati fi ope wa fun O 

     Pel’ awon ore wa 

     Ope ‘kore l‘a mu wa 

     F‘Oluwa ikore 

     Olorun, jo sokale wa 

     F’ogo Re kun ‘le yi.


3.  Larin ainiye ibi 

     T'o rogba yi wa ka 

     Larin ayida aiye yi 

     Lehin ‘kore esi 

     Awa f’ope fun O

     N'tori ‘Wo da wa si 

     Loni, odun ikore wa 

     A f‘ogo f’Oko Re.


4.  Gba Noa rubo ope 

     Wo f'osumare han

     Ami wi pe kikun omi 

     Ki o bo aiye mo 

     Baba f’osumare han 

     Nitori Jesu wa

     K’iponju on ibanuje 

     Mase tun de da wa.


5.  Obinrin opo ‘gbani 

     Ko ri pupo mu wa 

     Sugbon o ri ibukun gba 

     Fun iwon ti o le se 

     Jesu, yin wa loni 

     Je k’a ri ‘bukun gba 

     Tewogba ore ope wa 

     B’otile s’alaiye.


6.  Awa mbe O, Olorun

    Gba okan wa pelu

    Okan ese wa la mu wa 

    Egbin po ninu re

    F‘Eje Re mimo Jesu 

    We abawon re nu

    Ki okan ati ore wa 

    J’ebo ope fun o.  Amin

English »

Update Hymn