HYMN 729

(FE 755)
"Gba wa Olorun igbala wa" - Kro.16:35



1.  E dide omo-ogun gbala 

     Gbe oruko Jesu ga

     Fun ojo nla t’a ri loni

     Ti Maikeli Balogun wa.

Egbe: Maikeli Mimo Balogun 

           Maikeli Mimo Balogun 

           S’amona Egbe wa d'opin 

           B’awa segun Lusifa.


2.  A dupe pe o je tiwa 

     Larin Egbe Serafu

     Ko si b’esu tile gb’ogun 

     Maikeli a bori won.

Egbe: Maikeli Mimo...


3.  L’ojo na t’ogun gb’orun kan 

     Orun, aiye wariri

     lberu nla l'o gb’aiye kan 

     Maikiel f’oko e g’esu.

Egbe: Maikeli Mimo...


4.  Mo gb’ohun na lati orun wa 

     Pe egbe ni fun aiye

     A le olufisun s’aiye

     Awon ayanfe yio la.

Egbe: Maikeli Mimo...


5.  Egbe Kerubu ma beru 

     Pe Maikeli je tiwa

     Oso, aje ko n’ipa mo

     Lori Egbe Mimo yi.

Egbe: Maikeli Mimo...


6.  Jesu, Omo Mimo Baba

     A f;ogo f'Oruko Re 

     Pe Maikeli ti segun esu 

     Awon ogun esu fo.

Egbe: Maikeli Mimo...


7.  Gbati pe ‘kehin ba si dun 

     Olorun awa mbe O

     Ma jek’ owo esu te wa

     K‘a si le gb'ade iye.

Egbe: Maikeli Mimo Balogun 

           Maikeli Mimo Balogun 

           S’amona Egbe wa d'opin 

           B’awa segun Lusifa.  Amin

English »

Update Hymn