HYMN 712

t.H.C 366 8s 7s (FE 739)
“E wa wo awon ise Oluwa" - Ps. 46:8
Tune: s.s.l.s.d.d.I.s.d.m.d.s.m.r:‐



1.  EGBE Kerubu to jade 

     Awa lo ns’ajodun wa

     K’ogun orun ba wa gberin 

     K’araiye gbohun soke.

Egbe: Halleluya, Halleluya

          T'ewe t’agba ko gbe rin - 2ce


2.  Ope lo ye f’Olugbala

     Fun idasi wa oni

     Ota ka wa nibi gbogbo 

     Sugbon Jesu ko wa yo.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


3.  Emi Mimo ko pelu wa 

     L’okunrin at’lobinrin 

     kerubu pelu Serafu

     K’a pade n’ijo t’orun.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


4.  Olorun Olodumare

     Obangiji Oba wa

     Ma je k’ebi ale pa wa 

     K’enikeni ma pose.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


5.  Kerubu pelu ogun re

     Ni awon ariran nri

     Holy Maikeli pelu ‘da Re

     O ngesin po yi wa ka.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


6.  Abo Oluwa Onike

     L’awa Egbe bora mo

     Ko s’ohun ibi to le se wa 

     Lagbara Metalokan.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


7.  Eni l‘oyun a bimo la

     Agan a f’owo bosun

     Olomo ko ni padanu

     Iku ko ni ri wa gbe se.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


8.  Gbogbo awon ti ko ri se 

     L'okunrin l'obinrin

     Ipese Olodumare 

     Awamaridi lo je.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


9.  E wa ba wa k’Alleluya 

     F’odun miran Kerubu 

     T’Oluwa d'egbe na sile

     Iarin Egbe Serafu.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


10.  Oba aw’Egbe Kerubu

       Jesu Kristi Oluwa,

       Awa nkorin, awa si nyo

      Ogo fun Od’agutan.

Egbe: Halleluya, Halleluya

          T'ewe t’agba ko gbe rin

          T'ewe t’agba ko gbe rin.  Amin

English »

Update Hymn