HYMN 710

Tune: D 6s


1.  OGO, iyin, ola

     Fun Olugbala wa 

     T’o da eni wa si 

     Titi d'ojo oni

     Ayo kun okan wa 

     Fun anfani nla yi 
 
     Lati sise fun O 

     N’nu ogba re laye.


2.  A dupe fun toni

     On agbara t'erni 

     At’ebun ife nla

     Ti o fi so wa po 

    Olusagutan wa 

    Tewo gba iyin wa 

    Nitori anu Re 

    Se wa l’okan laelae.


3.  Bukun wa, Oluwa 

     Loni ajodun wa

     Ran ami Re si wa 

     K’a layo n'nu sin Re 

     Ka si s'aseyori

     N’nu ise isin wa 

     K’a si fi Jesu se 

     Igbekele wa lae.


4.  Eleda, Oluwa

     Orisun gbala wa 

     Se wa ye f’ajodun

     Ti ibugbe loke

     N‘ipari ajo wa

     N’nu aye osi yi

     K'a le ni ibugbe

     Lodo Re Oluwa.  Amin

English »

Update Hymn