HYMN 694

H.C 389 D. 7s (FE 719)
“Ko si Oluwa ninu Ina na ati iji 
nla bikose ninu ohun kele 
kekere" - 1Oba 19:12



1.  JEJE laisi ariwo

     Jeje sa ni orun nran 

     Gbat' o ba yo ni ila re, 

     Eda si le wo oju re 

     B‘o si ti ngoke pele 

     Jeje l‘agbara re npo 

     Titi y‘o fi kan tari 

     Nin’ogo t’a ko le wo.


2.  Okunkun t’o n’ipa ju

     Ko wa pelu okiki 

     Osupa ati Irawo

     Ti ntan ‘mole y‘aiye ka 

     Nwon ko wa pelu iro 

     lri nla ti o nse

     Yi gbogbo aiye yi ka 

     Ko wa pelu okiki.


3.  Bayi n’ise OLORUN 

     Larin EGBE MIMO yi 

     B’a ti je alailera 

     T'agbara wa ko si po 

     Sugbon ipese BABA 

     ‘Jojumo l'o nyo si wa 

     Nipa GBARA OLORUN 

     A ko ile na pari.


4.  Loni yi, OLORUN wa, 

     Awa Egbe Serafu 

     Omode ati agba 

     Okunrin at’Obinrin 

     Onile at’alejo

     T’o wa fi ope fun O 

     Ninu ile Mimo yi 

     Masai tewogb’ope wa.


5.  OLORUN METALOKAN 

     T’o da Egbe yi sile

     Ya ile yi si MIMO

     Nipa AGBARA nla re 

     Sokale l’ojo oni

     F’agbara wo gbogbo wa, 

     Ki gbogbo wa je TIRE 

     Laiye yi ati l’orun.  Amin

English »

Update Hymn