HYMN 639

(FE 665)
"Eniti o po Ii Anu ni Oluwa" - Num. 14:18



1.  OLORUN gbogbo araiye 

     Iwo t’o pe ki mole k'o wa 

     Iwo t’o pe k'eweko hu 

     O si ri be nipa ase Re.

Egbe:  Gbo t’emi, gbo t'emi 

            gbo t’emi

            Oba awimayehun 

            gbo t'emi - 3ce

            Oba a wi‐ma-yehun.


2.  Olorun t’o gbo ti Mose 

     T’a pa awon oba ko fi ka 

     Olorun t’o gbo t’Elija 

     T’o si doju t'awon ota re. 

Egbe:  Gbo t’emi, gbo t'emi...


3.  Olorun t'o pe k'okun wa 

     T’omo araiye ko ri di re 

     Olorun t‘o pe k’osa wa 

     T'omo araiye ko ri di re. 

Egbe:  Gbo t’emi, gbo t'emi...


4.  Olorun t’o la gan ninu 

     Baba awon alaini baba 

     Olorun t’o gbo ti Estha

     T'o si gbe leke awon ota re. 

Egbe:  Gbo t’emi, gbo t'emi...


5.  Kerubu pelu Serafu

     F’ogo fun Baba loke 
    
     Fun isegun t’o nse fun wa 

     Nigbat’awon aiye fe kegan. 

Egbe:  Gbo t’emi, gbo t'emi...


6.  E f’ogo fun Baba loke 

     A wa si f'ogo f’omo Re 

     A f’ogo fun Emi Mimo 

     Metalokan ni ope ye fun.

Egbe:  Gbo t’emi, gbo t'emi 

            gbo t’emi

            Oba awimayehun 

            gbo t'emi - 3ce

            Oba a wi‐ma-yehun.  Amin

English »

Update Hymn