HYMN 635

C.M.S 475 H.C 411 2nd Ed. H.C 470 
6s, 8s (FE 661)
“Ma wi, nitori omo-odo Re ngbo" - 1Sam.3:9



1.  GBATI Samueli ji 

     T'o gb’ohun Eleda

     Ni gbolohun kokan 

     Ayo re ti po to

     Ibukun ni f’omo t‘o ri 

     Olorun nitosi re be.


2.  B'Olorun ba pe mi 

     Pe, ore mi li On

     Ayo mi y'o ti to 

     Ngo si f’eti sile

     Ngo sa f’ese t‘o kere ju 

     B’Olorun sunmo ‘tosi be.


3.  Ko ha mba ni soro? 

     Beni, n'nu Oro Re 

     O npe mi lati wa 

     Olorun Samueli

     N'nu lwe na ni mo ka pe 

     Olorun Samuel npe mi.


4.  Mo le f’ori pamo 

     S’abe itoju Re

     Mo mo p’Olorun mbe 

     Lodo mi n'gbagbogbo

     O ye k’eru ese ba mi 

     Tor’ Olorun sunmo 'tosi.


5.  Gba mba nka oro re

     Ki nwi bi Samuel pe

     Ma wi, Oluwa mi

     Emi y‘o gbo Tire

     Gba mo ba si wa n'ile Re

     Ma wi tori ranse Re, ngbo.  Amin

English »

Update Hymn