HYMN 609

C.M.S 73 H.C 65 2nd Ed 8.7.4 (FE 635)
“Wakati mbo ninu eyiti gbogbo awon ti
o wa ni isa oku yio gbo ohun re, nwon 
o si jade wa” - John 5:28




1.  OJO ‘dajo ojo eru! 

     Gbo bi ipe ti ndun to! 

     Oju egberun ara lo 

     O si nmi gbogbo aiye 

     Bi esun na

     Y’o ti damu elese.


2.  Wo Onidajo l’awo wa

     T'o wo ogo nla l‘aso 

     Gbogbo nwon ti nwo ona Re 

     Gbana ni nwon o ma yo

     Olugbala

     Jewo mi ni ojo na.


3.  Ni pipe Re oku o ji 

     Lat' okun, ile s’iye

     Gbogbo ipa aiye y’o mi 

     Nwon o salo loju Re 

     Alaironu

     Yio ha ti ri fun o?


4.  Esu ti ntan o nisiyi 

     Iwo mase gbo tire 

     Gbati aiye yi ba koja 

     Y’o ri o ninu ina 

     Iwo ronu

     Ipo re ninu ina.


5.  Labe iponju at‘egun 

     K’eyi gba o n’ iyanju 

     Ojo Olorun mbo tete 

     'Gbana ekun y’o d’ayo 

     A o segun

     Gbati aiye ba gbina.  Amin


English »

Update Hymn