HYMN 608

C.M.S 404 t. S. 675 D. 85 (FE 634)
“Nibo ni iwo wa" - Gen. 3:9



1.  NlGBAT’ idanwo yi mi ka 

     Ti idamu aiye mu mi 

     T‘ota fara han bi ore

     Lati wa iparun fim mi.

Egbe: OIuwa, jo ma sai pe mi 

          B’o ti pe Adam nin'ogba 

          Pe’ Nibo I’o wa elese?

          Ki nIe bo ninu ebi na.


2.  Nigbat’Esu n’nu ‘tanje re 

     Gbe mi gori oke aiye

     T’o ni ki nteriba fun on 

     K'ohun aiye le je temi

Egbe: OIuwa jo...


3.  Gbat' ogo aiye ba fe fi 

     Tulasi mu mi rufin Re 

     To duro gangan lehin mi 

     Ni ileri pe’Ko si nkan.

Egbe: OIuwa jo...


4.  Nigbati igbekele mi 

     Di t’ogun ati t’orisa 

     T’ogede di adura mi 

     Ti ofo di ajisa mi.

Egbe: OIuwa jo...


5.  Nigbati mo fe lati rin 

     L’adamo at’ife n’nu mi 

     T’okan mi nse hila-hilo 

     Ti nko gbona, ti nko tutu. 

Egbe: OIuwa jo...


6.  Nigba mo sonu bi aja 

     Laigbo ifere ode mo 

     Ti nko nireti ipada

     Ti mo npafo ninu ese.

Egbe: OIuwa jo...


7.  Nigbati ko s’alabaro

     Ti Olutunu si jina

     T’ibanuje b’iji lile

     Te ori mi ba n’ironu.

Egbe: OIuwa, jo ma sai pe mi 

          B’o ti pe Adam nin'ogba 

          Pe’ Nibo I’o wa elese?

          Ki nIe bo ninu ebi na.  Amin

English »

Update Hymn