HYMN 581

H.C 357 11s (FE 608) 
"So fun awon omo Isreal pe ki
nwon tesiwaju" - Eks. 14:15



1.  E MA te siwaju, Serafu mimo 

     Gbe ‘da segun soke s’esu ati ese 

     Baba Olusegun ti segun fun wa 

     E ma beru larin ainiye ota

     K’a se fe Oluwa, b’ara igbani 

     On to gbo t’Abrahamu

     Yio gbo tiwa.


2.  E ma te siwaju, Kerubu mimo 

     O di jeriko wo nipa orin won

     Lati ipa de ‘pa nwon nko ikogun 

     Tesiwaju larin ainiye egan

     K'a se 'fe Oluwa, b’ara igbani 

     On to gbo ti Mose, yio gbo tiwa.


3.  Ranti agbara Re niwaju oba ni 

     Ranti isegun Re ni okun pupa 

     Owo Awosanmo li osan gangan 

     Ati owon ina Re fun won l'oru 

     K’a se fe Oluwa, b'ara igbani

     On to gbo ti Joshua, yio gbo ti wa.


4.  Baba Olupese yio pese fun wa 

     Ranti ipese re ninu aginju

     Lati ‘nu apata o fun won l'omi

     O fi manna ati aparo bo won

     Kas e fe Oluwa b’ara igbani 

     On to gbo ti Daniel, yio gbo itwa.


5.  E ma te siwaju, bi ‘danwo ba de 

     E sa kun f’adura, e o si bori 

     Agbara Oluwa li abo fun wa

     Ranti Sedrak, Mesaki at’Abednigo 

     K'a se fe Oluwa b‘ara igbani 

     On to gbo t‘Elijah, yio gbo tiwa.


6.  Serafu t’aiye yi, eku ajodun 

     Kerubu t’aiye yi, e ku ajodun 

     Ajodun nla kan mbo ti ao se loke 

     Pelu awon Mimo lati yin Baba 

     Ka se ‘fe Oluwa, b’ara igbani 

     Metalokan Mimo yio gbo tiwa.  Amin

English »

Update Hymn