HYMN 57

H.C 177 T.S 43 P.M (FE 74) 
“Gba awon enia Re la" - Ps. 28:9
Tune: “Mokandinlogorun dubule je"



1.  GBA WA lojo na t’ ao se ‘dajo aiye,

      K'awa le j'eni ‘tewogba

     Se iranlowo fun wa ka j'eni

     ‘tewogba

     Sibi omi ‘ye t'O pese.

Egbe:  Sanu fun wa gbadura wa,

            Ji okan ti ntogbe kuro nin'ese. 2ce


2.  Jowo tan imole Re loni Oluwa,

     S'oju awon ti ko riran

     Ni apa Jesu aye wa sibe

     Mase tun wi awawi mo.

Egbe:  Sanu fun wa...


3.  Enyin lmale ati Keferi,

     E wa gbo ihin rere yi,

     Akoko na mbo t’a o bere lowo re

     Pe ise kini iwo nse?

Egbe:  Sanu fun wa...


4.  Enyin Egbe Kerubu ati Serafu

     E j‘arowa e ma w'ehin

     Lo wo Isaiah ori ogota,

     Ese kini ati keji.

Egbe:  Sanu fun wa...


5.  Enyin ero iworan ati enijoko

     Bi‘dajo ba o nin‘ese nko

     E wa si imole ninu Egbe Serafu,

     Ke ba le j’eni ‘tewogba.

Egbe:  Sanu fun wa...


6.  Gbogbo Omo Egbe t‘o s‘olotito

     Ade ogo ti wa fun nyin,

     Bohubiea Aleakutatabb

     Ko ni jeki gbogbo wa segbe

Egbe:  Sanu fun wa...


7.  Enyin agan to wa ninu Egbe

     E mura si ‘gbagbo,

     Ki e le ni omo bi Samueli

     Lodo Olodumare.

Egbe:  Sanu fun wa...


8.  Enyin Alamodi to wa  nin‘ Egbe

     Enyin yio si ri 'wosan gba

     Lat’odo onisegun Jerusalemu

     E o ri imularada.

Egbe:  Sanu fun wa...


9.  Enyin ti e ko ti ri ‘se se,

     Jehofa Jireh yio pese,

     lse rere fun itelorun nyin,

     E o ri tunu gba.

Egbe:  Sanu fun wa...


10.  Ogo ni fun Baba loke

       Ogo ni fun Omo,

       Ogo ni fun Emi Mimo

       Metalokan lailai.

Egbe:  Sanu fun wa...  Amin

English »

Update Hymn