HYMN 549

C.M.S 435 H.C 339 L.M (FE 575)
"Awa o lo sinu ago, Re awa o ma 
sin nibi apoti agbara Re" - Ps.132:7




1.  ODO-Agutan Olorun

     Jo we mi ninu eje Re

     Sa je ki nmo ‘fe Re, gbana 

     lrora dun, iku lere.


2.  Fa okan mi kuro l‘aiye 

     K'o je k'o se Tire titi 

     Fi edidi Re s'aiya mi 

     Edid’ife titi aiye.


3.  A! awon wonni ti yo to

     To f’iha Re se 'sadi won 

     Nwon fi O se agbara won

     Nwon nje, nwon si nmu ninu Re.


4.  O kun wa loju p’Olorun 

     Fe m' awa yi lo sin ‘ogo 

     Pa, O so eru d’om‘Oba 

     Lati ma je faji lailai.


5.  Babe, mu wa ronu jinle

     K‘a le mo ise nlanla Re

     Ma sai tu okun ahon wa

     K’a le so ibu ife re.


6.  Jesu, Iwo l’Olori wa,

     Wo lao teri wa ba fun

     Wo l’ao fi okan wa fun

     B’a ku, b’a wa, k’a je Tire.  Amin

English »

Update Hymn