HYMN 532

O.t.S 670 S.M. (FE 558)
“Nkan wonyi ni mo palase fun nyin pe 
ki enyin ki o fe omomikeji nyin"
 - John 15:17




1.  FE enikeji re

     Ase Oluwa ni

     O wa f‘ara Re s'apere 

     Ni ifefe t'O fe wa.


2.  Fe enikeji re"

     N’ire tabi n’ija

     O ko wa pe k’a f'ota wa 

     K’a f’ore san ibi.


3.  Fe enikeji re’

     Oluwa nke tantan

     O ye ki gbogbo wa mura 

     K’a f 'enikeji wa.


4.  Fe enikeji re 

     At’aladugbo re

     Pelu gbogb’eni yi o ka 

     At' ota re pelu.


5.  K‘a f'enikeji wa

     Bi Jesu ti fe wa

     Jesu sa f'awon ota Re 

     O si sure fun won.  Amin

English »

Update Hymn