HYMN 525

C.M.S 336 H.C 328 t. H.C 
449 6. 7s (FE 550)
"Ara, ajigbese Ii awa" - Rom. 8:12



1.  GBAT‘AYE yi ba koja 

     T’orun re ba si won 

     Ti a ba won ‘nu ogo

     T‘a boju wo ehin wa 

     Gbana, Oluwa, ngo mo 

     Bi gbese mi ti po to.


2.  Gba mo ba de b’ite Re 

     Lewa ti ki se t’emi 

     Gba mo ri O b’O ti ri 

     Ti mo fe O l'afetan 

     Ghana, Oluwa ngo mo 

     Bi gbese mi ti po to.


3.  Gba mba ngbo orin orun 

     Ti ndun bi ohun ara

     Bi iro omi pupo

     To o si ndun b’ohun duru 

     Gbana, Oluwa, ngo mo

     Bi gbese mi to po to.


4.  Oluwa, jo, je k'a ri 

     Ojiji Re l’aiye yi 

     K’a mo adun ‘dariji 

     Pelu iranwo Emi

     Ki ntile mo l‘aiye yi 

     Die ninu ‘gbese mi.


5.  Ore-ofe l’o yan mi

     L’o yo mi ninu ewu

     Jesu l‘Olugbala mi

     Emi so mi di mimo

     Ko mi, ki nfihan l’aiye,

     Bi gbese mi ti po to!.  Amin

English »

Update Hymn