HYMN 516

C.M.S 332 H.C 321 C.M (FE 541)
"Ife Krist li o nro wa" 2Kor.5:14.




1.  OLUGBALA mi, ife Re 

     Ha tobi be si mi

     Wo mo f’ile mi, okan mi 

     At'aiya mi fun O.


2.  Mo fe O nitori ‘toye 

     Ti mo ri ninu Re 

     Mo fe O nitori iya 

     T‘o f'ara da fun mi.


3.  Bi Iwo ti je Olorun 

     T'a f’ogo de l’ade 

     Iwo ko ko awo enia 

     T’o kun fun iyonu.


4.  Wo je k’a bi O l’enia 

     Sugbon ‘Wo ko l’ese 

     K’awa le ri b‘Iwo ti ri 

     K’a le se b'O ti se.


5.  K’a dabi Re ninu ife 

     L’ewa iwa mimo

     B’a ti nwoju Re, k’a ma lo 

     Lat’ogo de ogo.  Amin

English »

Update Hymn