HYMN 448

(FE 473)
"lwo ki yio beru nitori eru oru"
 - Ps. 91:5



1.  ENYIN Omo Egbe Kerubu 

     Ma beru, ma sojo

     Oluwa l’o n ran wa n’ise 

     Awa ki yio beru.

Egbe:  Baiye nsata pelu Esu 

           Eke ni won, nwon nse lasan

           B’aiye nsatan, pelu esu

           Eke ni nwon, nwon nse lasan.


2.  Enyin Omo Egbe Serafu 

     Ma je k’oju ti nyin 

     lse Oluwa l’a wa nje 

     Awa ki yio tiju.


Egbe:  Baiye nsata pelu Esu...


3.  Enyin Egbe Aladura

     E mura s‘ise nyin 

     Gbogbo ise nyin ti e nse 

     Okan ko lo lasan.

Egbe:  Baiye nsata pelu Esu...


4.  Enyin Omo Egbe Bibeli 

     E mura s’adura 

     K’Olorun la oju emi nyin 

     Lati rohun ijinle.

Egbe:  Baiye nsata pelu Esu...


5.  Enyin Omo Egbe Akorin 

     E tun ohun nyin se,

     Orin l’awa yio ko lorun 

     A ko n‘ise miran.

Egbe:  Baiye nsata pelu Esu...


6.  E’ogo fun Metalokan 

     Baba Omo, Emi

     Titi aiye ainipekun

     Amin! beni ki o ri.

Egbe:  Baiye nsata pelu Esu 

           Eke ni won, nwon nse lasan

           B’aiye nsatan, pelu esu

           Eke ni nwon, nwon nse lasan.  Amin

English »

Update Hymn