HYMN 409

(FE 430) C.M.S 299, t.H.C 233 L.M
"Nibe l'emi o pada re, emi o si ba o 
soro lati oke ite anu wa” - Eks. 25:22



1.  NINU gbogbo iji ti nja 

     Ninu gbogbo igbi’ponju 

     Abo kan mbe ti o daju

     O wa labe ite‐anu.


2.  Ibi kan wa ti Jesu nda 

     Ororo ayo sori wa

     O dun ju ibi gbogbo lo 

     Ite anu t’a f’eje won.


3.  Ibi kan wa fun idapo

     Nibi ore npade ore

     Lairi ‘ra nipa igbagbo

     Nwon y’ite anu kanna ka.


4.  A! nibo ni a ba sa si 

     Nigba ‘danwo at’iponju?

     A ba se le bori esu,

    B’o se pe ko si ‘te-anu.


5.  A! bi idi l’a fo sibe 

     B’enipe ajye ko si mo 

     Orun wa pade okan wa 

     Ogo si bo ite‐anu.  Amin

English »

Update Hymn