HYMN 370

C.M.S. 254 8s. 8s. 6s (FE 392)
“Awa nyo ni ireti Ogo Olorun"
 - Rom. 5:2



1.  LEHIN aiye buburu yi 

     Aiye ekun on osi yi

     Ibi rere kan wa

     Ayipada ko si nibe

     Ko s’oru af'osan titi 

     Wi mi, ‘wo o wa nibe?


2.  “Lekun ogo re ti m’ese" 

     Ohun eri ko le we ‘be

     Lati b‘ewu re je 

     L’ebute daradara ni,

     A ko ni gburo egun mo 

     Wi mi, ‘wo o wa nibe?


3.  Tani o de ‘be? Onirele 

     To f'iberu sin Oluwa

     T'won ko nani aiye

     Awon t'a f'Emi Mimo to 

     Awon t‘o nrin l’ona toro 

     Awon ni o wa nibe?  Amin

English »

Update Hymn