HYMN 251

C.M.S 157.H.C.162 L.M (FE 271)
“Nigbana ni o sanu fun, o si wipe gba kuro 
ninu lilo sinu: iho, emi to ri irapada"
 - John. 33:24



1.  BI mo ti kunle, Oluwa

     Ti mo mbe f’anu lodo Re 

     Wo t’Ore lese ti nku lo 

     Si tori Re gb'adura mi.


2.  Ma ro ‘tiju at' ebi mi

     At' aimoye abawon mi 

     Ro t’eje ti Jesu ta ‘le 

     Fun ‘dariji on iye mi.


3.  Ranti bi mo ti je Tire

     Ti mo je eda owo Re 

     Ro b'okan mi ti fa s’ese 

     Bi danwo si ti yi mi ka.


4.  A! ronu oro mimo Re 

     Ati gbogbo ileri Re 

     Pe ‘Wo o gbo adua titi 

     Ogo Re ni lati dasi.


5.  A! ma ro ti ‘yemeji mi 

     Ati ailo or-ofe Re

     Ro ti omije Jesu mi

     Si fi toju Re di temi


6.  Oju on eti Re ko se

     Agbara Re ko le ye lai

     Jo wo mi; okan mi wuwo 

     Da mi si, k’O ran mi lowo.  Amin

English »

Update Hymn