HYMN 162

O. t. H. C. 519. 7s 6s (FE 181)
“Ongbe re ngbe akan mi bi ile gbigbe" 
- PS. 143:6



1.  EMI Mimo sokale

     Fi ohun orun han

     K’o mu imole w'aiye

     Si ara enia,

     K’awa t‘a wa I'okunkun 

     Ki o le ma riran

     ‘Tori Jesu Kristi ku, 

     Fun gbogbo enia.


2.  K’o fi han pe elese

     Ni emi nse papa

     K’emi k’o le gbeke mi, 

     Le Olugbala mi, 

     Nigbati a we mi nu 

     Kuro ninu ese 

     Emi o le fi ogo,

     Fun Eni-Mimo na.


3.  K‘o mu mi se aferi 

     Lati to Jesu lo;

     K'o joba ni okan mi, 

     K’o so mi di mimo 

     Ki ara ati okan

     k’o dapo lati sin 

     Olorun Eni-Mimo 

     Metalokan soso.  Amin

English »

Update Hymn