HYMN 120

C.M.S.239, t.H.C 222, L.M (FE 137)
"Emi o so ti iseun ife Oluwa" - Isa. 63:7



1.  JI, Okan mi, dide layo

     Korin iyin Olugbala

     Ola Re bere orin mi 

     Seun ife Re ti po to!


2.  O ri mo segbe n’isubu 

     Sibe, O fe mi l‘afetan 

     O yo mi ninu osi mi, 

     Seun ‘fe Re ti tobi to!


3.  Ogun ota dide si mi

     Aiye at‘Esu ndena mi

     On nmu mi la gbogbo re ja 

     ‘Seun ‘fe Re to n’ ipa to!


4.  Gba ‘yonu de, ba'awosanma, 

     T‘o su dudu t‘o nsa ara

     O duro ti mi larin re:

     ‘Seun ‘fe Re to dara to!


5.  ‘Gbagbogbo l’okan ese mi 

     Nfe ya Iehin Oluwa mi; 

     Sugbon bi mo ti ngbagbe Re, 

     lseun ife Re ki ye.


6.  Mo fere f‘aiye sile na, 

     Mo fe bo low'ara iku;

     A! k’emi ‘kehin mi korin 

     lseun lfe Re n’iku.


7.  Nje ki nfo lo, ki nsi goke 

     S‘aiye imole titi lai;

     Ki nf’ayo iyanu korin 

     lseun ife Re lorun.  Amin

English »

Update Hymn