HYMN 98

(FE 115)
‘Ibukun Ii Oruko Oluwa lati isisiyi
lo ati si i lailai" - Ps. 113:2



1.  ENYIN egbe Serafu,

     Wa fi ayo nyin han,

     E jumo ko orin didun

     Fun se‘yanu to se fun wa

     Ti ko je ka sonu kuro ni ona Re.

Egbe:  A nyan lo si Sion,

           Sion to dara julo

           A nyan goke lo si Sion

           Ilu Olorun wa.


2.  Baba Aladura

     F'ope fun Olorun

     To mu O bori awon ota

     Ti ko je ki ota yo o

     To fi o se ori

     Yio fi o se d’opin.

Egbe:  A nyan lo...


3.  Enyin Egbe Akorin

     E fi ayo nyin han

     Fun Majemu Re ti ko ye,

     Ni arin Egbe Serafu

     To mu se di oni,

     Ati aiye ti mbo.

Egbe:  A nyan lo...


4.  Enia Ie ma kegan

     Nwon si le ma sata

     Awon ti ko m'Olorun wa,

     Sugbon awa Egbe Kerubu

     A si m'eni t‘a nsin

     Yio si fun wa lere.

Egbe:  A nyan lo...


5.  Kerubu Serafu

     E mura sis'Emi

     Enyin yio sise na dopin

     E o si ri Olugbala

     L‘aye mimo loke

     Ati I’orun pelu.

Egbe:  A nyan lo...  Amin

English »

Update Hymn