HYMN 97

(FE 114)



1.  OLORUN Eleda t’o d'egbe Seraf,

     Ati Kerubu s'orile ede aiye

     Lat‘owo Jesu Olugbala owon

     Awa nyin oruko Re logo.

Egbe:  A! e ku ayo, eku ayo
  
           egbe Serafu

           A! e ku ayo, e ku ayo

           egbe Kerubu.


2.  Nibo l'awon ayanfe Olorun wa?

     E wa gbo ohun Oluso-agutan yi

     E ronu piwada, e wa w'oko na;

     Igbala na ku si atel'owo.

Egbe:  A! e ku ayo...


3.  Egbe Kerubu, dupe lowo Olorun

     Tesiwaju ninu ogun emi jija

     E fere gbo ‘hun Oluwa wa Jesu,

     Wipe, o seun, omo rere.

Egbe:  A! e ku ayo...


4.  Enyin ti nkoja lo ya sodo Jesu

     Lati gb‘ore-ofe n‘nu egbe yi,

     Mase kegan oko igbala ‘kehin

     T'Olorun Metalokan fun wa.

Egbe:  A! e ku ayo...


5.  Jesu Oluwa mbowa joba laiye
 
     Larin Egbe Kerubu ati Serafu

     Egberun Odun ni ‘joba re ninu

     Egbe Mimo at'oke wa yi.

Egbe:  A! e ku ayo...


6.  Jesu Kristi Oluwa Oba Ogo

     L'opa iye ainipekun wa lowo re

     Yio ko gbogbo awon t’o gbagbo Io,

     Siwaju ite baba l'oke.

Egbe:  A! e ku ayo...  Amin

English »

Update Hymn