HYMN 95

(FE 112)
"Efi ope fun Oluwa" - Ps. 105:11.  EJE ka jumo f’ope f'Olorun

     Orin iyin, at'ope lo ye wa,

     Iyanu n'ife Re si gbogbo wa,

     E korin ‘yin s’Oba Olore wa.

Egbe:  Halleluyah Ogo ni fun Baba

           A f'ijo, ilu yin Olorun wa,

           Alaye ni o yin O, bo ti ye

           Halleluya! Ogo ni fun Baba.


2.  Kil‘ a fi san j’awon t'iku ti pa?

     Iwo lo f’owo wo wa di oni

     ‘Wo lo nso wa to ngba wa lo'ewu

     E korin 'yin s'Olutoju wa.

Egbe:  Halleluyah Ogo...


3.  Gbogbo alaye I'O nfun l'onje won,

     Iwo lo npese f‘onikaluku;

     Iwo lo nsike eda Re gbogbo

     E korin ‘yin si Oni bu‐Ore.

Egbe:  Halleluyah Ogo...


4.  Ohun wa ko dun to lati korin

     Enu wa ko gboro to fun ope

     B'awa n'egberun ahon nikokan

     Nwon kere ju lati gb’ola Re ga.

Egbe:  Halleluyah Ogo...


5.  Gbe wa leke ‘soro l‘ojo gbogbo

     Fun wa l'ayo at'alafia Re,

     Je k'a ri bukun gba lo ‘le wa,

     K'a ba le wa f'ogo f’oruko Re.

Egbe:  Halleluyah Ogo...


6.  Enyin Angeli l‘orun wa ba wa gbe

     Orin iyin at’ope t'o ye wa

     S'Oba wa aiku Olola-julo

     Oba wa Jehofa t'o joba.

Egbe:  Halleluyah Ogo...  Amin

English »

Update Hymn