HYMN 94

(FE 111)
"Gbe a gbo" - Job 5:27



1.  JESU mo wa sodo Re,

     Je ki nle ma to O lehin

     Bi ‘ni mi gbogbo po si

     Ti ero mi gbogbo soji.

Egbe:  E yin logo, enyin Mimo

           E f’ope fun Baba loke

           Da wa si I'egbe Serafu,

           Ni kehin gba okan wa la.


2.  Keferi, lmale, e wa

     Onigbagbo, ma kalo

     K‘a jo yin Olorun wa,

     K‘a le d'ade ni ‘kehin.

Egbe:  E yin logo...


3.  A dupe lowo Olorun

     T'o fi Jesu Kristi fun wa

     Lati ra araiye pada,

     Lowo ese at’Esu.

Egbe:  E yin logo...


4.  Egbe Serafu damure

     Egbe Kerubu kun f 'adura

     Olugbala yio gba wa la

     Oluwosan yio wo wa san

Egbe:  E yin logo...


5.  Ojo mbo t‘aiye yio pin

     E sora enyin Mimo

     K'eni waju te siwaju

     K'eni ehin ma jafara.

Egbe:  E yin logo...


6.  Awon to segun saju

    Nwon nwo wa b’a ti nyo loni,

    Nwon nkan sara si wa wipe

    Te siwaju, ma fa s'ehin.

Egbe:  E yin logo...


7.  Ma siyemeji lona yi,

     B'o ti wu k'o le fun o to;

     Serafu mase foiya

     Adun y‘o kehin aiye re.

Egbe:  E yin logo...


8.  Nigbati ‘pe kehin ba dun

     Jesu y‘o ko wa de Kenaani,

     Je ka l'ayo lodo Re

     Fi wa s'agbala itura.

Egbe:  E yin logo...


9.  E f'ogo fun Baba Ioke

     E f'ogo fun Omo pelu

     E f'ogo fun Emi Mimo

     Metalokan lope ye fun.

Egbe:  E yin logo...  Amin

English »

Update Hymn