HYMN 93

C.M.S 44, H.C 55, P.M (FE 110)
"Olorun yi, Olorun wa ni lai ati
lailai” - Ps. 48:14



1.  A F‘OPE f‘Olorun.

    L'Okan ati Ohun wa,

    Eni ns'ohun ‘yanu,

    N'nu Eniti araiye nyo

    Gbat' a wa l'om‘owo

    On na l'o ntoju wa,

    O si nf’ebun ife

    Se ‘toju wa sibe.


2.  Oba Onib’ore

     Ma fi wa sile lailai

     Ayo ti ko l'opin

    On bukun y'o je tiwa

    Pa wa mo n’nu ore

    To wa gba ba damu

    Yo wa ninu ibi

    Laiye ati l‘orun.


3.  K’a f’iyin on ope

     F’Olorun Baba Omo,

     At‘Emi Mimo

     Ti o ga julo I’Orun

     Olorun kan lailai

     T'aiye at'orun mbo

     Be l'o wa d'isiyi

     Beni y'o wa lailai.  Amin

English »

Update Hymn