HYMN 92

C.M.S. 568,  8.7.8.7.4.7  (FE 109)
“Fi ibukun fun Oluwa, iwo okan mi"
- Ps.104:1



1.  OKAN mi yin Oba orun

     Mu ore wa sodo Re,

     ‘Wo ta wosan, ta dariji

     Tal‘a ba ha yin bi Re?

Egbe:  Yin Oluwa, Yin Oluwa
            
            Yin Oba Ainipekun

            Yin Oluwa, Yin Oluwa
            
            Yin Oba Ainipekun


2.  Yin fun Oko ‘gbala kehin

     To sokale f'araiye

     O si yan Bab'Aladura

     Lati je Alakoso.

Egbe:  Yin Oluwa...


3.  Yin fun anu to ti fihan

     Lori Egbe Serafu;

     To pa wa mo titi d'oni

     To si fun wa n'isegun.

Egbe:  Yin Oluwa...


4.  Yin fun abo ti o daju

     To nfun wa lojurere,

     Ninu wahala on ‘danwo

     Anu Re wa bakanna.

Egbe:  Yin Oluwa...


5.  Yin fun abo ti o daju

     Ta nri l'Egbe Serafu

     Aje, Oso, on Sonponnna

     Won ko ri wa gbese mo

Egbe:  Yin Oluwa...


6.  Bi baba ni o ntoju wa

     O si mo ailera wa,

     Jeje lo ngbe wa I'apa Re,

     O nf‘ onje iye bo wa.

Egbe:  Yin Oluwa...


7.  Ogun orun, e ba wa yin

     Baba, Omo, on Emi

     Orun, Osupa, e wole

     Ati gbogbo agbaiye.

Egbe:  Yin Oluwa...  Amin

English »

Update Hymn