HYMN 9

C.M.S 17, H.C 25, L.M (FE 26)
"Nigbati o si di asale, ti orun wo, nwon
ko gbogbo awon olokunrun 
to o wa" - Marku 1:32


1.  L'OJU ale, ‘gbat’ orun wo,

     Nwon gbe abirun w'odo Re; 

     Oniruru ni aisan won,

     Sugbon nwon f‘ayo lo le won.


2.  Jesu a de loj’ ale yi,

     A sunmo O t’awa t'arun wa, 

     Bi a ko tile le ri O,

     Sugbon a mo p’O sunmo wa


3.  Olugbala, wo osi wa, 

     Omi ko san, ‘mi banuje 

     Omi ko ni ife si O,

     Ife elomi si tutu.


4.  Omi mo pe asan l'aiye 

     Beni nwon ko f'aiye sile 

     Omi l'ore ti ko se ‘re 

     Beni nwon ko fi O s‘ore.


5.  Ko s’okan ninu wa t'o pe 

     Gbogbpo wa si ni elese 

     Awon t’o si nsin O toto 

     Mo ara won ni alaipe.


6.  Sugbon Jesu Olugbala 

     Eni bi awa ni Iwo se 

     ‘Wo ti ri danwo bi awa 

     'Wo si ti mo ailera wa.


7.  Agbar‘owo Re wa sibe

     Ore Re si ni Agbara,

     Gbo adura ale wa yi,

     Ni anu, wo gbogbo wa san.  Amin

English »

Update Hymn