HYMN 89

1.  OLORUN mi, ‘gba ti mo f'eru ‘yanu

     Kiyesi ise ti owo re se

     Mo ri ‘rawo, mo gb’ohun

     aara rti nsan

     Agbara re tan ka gbogbo aye.

Egbe:  Okan mi ko ‘rin si

           Oluwa re

           Alagbara I’Olorun mi!

           Okan mi ko ‘rin si

           Oluwa re

           Alagbara l'OIorun mi.


2.  ‘Gba ti mo rin kaakiri ninu igbo

      Mo gbo t’awon eye n ko ‘rin didun

     ‘Gba mo wo ‘le lat’ ori oke giga

     T’odo n san, t’afefe si fe si mi

Egbe:  Okan mi ko ‘rin si...


3.  ‘Gba ti mo ro o pe ko da Omo re si

     Lati wa ku, mo roju gba a gbo pe

     O r'eru ese mi lo lori igi

     O t’eje Re sile, O ku fun mi.

Egbe:  Okan mi ko ‘rin si...


4.  ‘Gba Kristi yoo de pelu orin ‘segun

      Wa mu mi lo, ayo yoo gb‘okan mi!

      'Gba naa ngo juba, ngo f’irele wole

      Ngo kede ‘titobi I'Olorun mi!.

Egbe:  Okan mi ko ‘rin si...  Amin

English »

Update Hymn