HYMN 88

S.S. & S. 209 (FE 105)
"F’ibukun fun Oluwa, iwo okan
mi" - Ps. 104:1



1.  A YIN Oba Ogo, On li Olorun

     E yin fun 'se yanu ti O se fun wa

     Fun siso t'o nso wa ni ojo gbogbo

     Fun owo ina ati awosanma.

Egbe:  Enyin Angeli didan

           fi Harpu wura yin

           Enyin Ogun Orun t'e nri oju Re

           Yika gbogbo aiye titi?

           Lai n’ise Re y’o ma yin

           Fi ibukun f ’OIuwa iwo okan mi.


2.  E yin fun igbala to fun wa l’ofe

     E yin fun Orisun to le we wa mo

     E yin fun ore ati itoju Re,

     E yin pelu pe O ngbo adura wa.

Egbe:  Enyin Angeli...


3.  E yin fun idanwo, ti o nran si wa

     Lati fi s'okunfa wa s‘odo ‘ra Re

     E yin fun igbagbo lati ma segun

     E yin fun ‘leri ilu orun rere.

Egbe:  Enyin Angeli...  Amin

English »

Update Hymn