HYMN 87

(FE 104)
“E ma yin Oluwa” Ps. 112:1
Tune: Ma toju mi Jehovah nla.



1.  OPE lo ye f’Olugbala

     Iyin fun Metalokan

     T’O da wa si d’ojo oni,

     A f'ogo f‘oruko Re.

Egbe:  Korin Ogo, Alleluya,

           Orin ogo lao ko

           Korin Ogo, Alleluyah,

           Ko Hosannah s'Oba wa.


2.  Metalokan Oba Ogo

     Baba fun wa l’agbara

     F’awon asaju n’isegun

     Fun won l’ogbon at’oye

Egbe:  Korin Ogo...


3.  Obangiji Oba Ogo,

     Ranti Egbe Aladura,

     Fun won l‘agbara at'ife

     Ko won l'adura t'orun.

Egbe:  Korin Ogo... 


4.  Jehovah-Nissi Oba wa,

     Sanu f’Egbe Serafu;

     F’isegun f’Egbe Kerubu

     Se wa gege bi t’orun.

Egbe:  Korin Ogo... 


5.  Awon ti ko ri ‘se yio ri,

     Agan a f’owo s’osun

     Olomo ko ni padanu,

     Alaisan yio dide.

Egbe:  Korin Ogo... 


6.  Gbo tiwa Baba wa orun

     Ranti Egbe idale,

     Fun won l’agbara at’ipa

     Fun gbogbo wa n'isegun

Egbe:  Korin Ogo... 


7.  Jehovah Shammah Oba wa,

     Gbat’ o ba d‘ojo ikehin

     Mu wa d’agbala itura,

     JAH mu wa de ‘te Ogo.

Egbe:  Korin Ogo...   Amin

English »

Update Hymn