HYMN 865

1.  OLUWA awa de

     Kerubu, Serafu 

     Lati je ise to ra wa 

     Fun gbogbo agbaiye.


2.  lse t’o ran l’eyi

     Olorun Oluwa

     P’a won ti nb’ojo isimi je 

     Ni yio jebi poju.


3.  K’araiye teriba 

     Niwaju ase Re 

     K’ibinu Olodumare 

     Le ka kuro l’aiye.


4.  Kerubu Serafu 

     Enyin n’iyo aiye 

     Iluu t’a te sori oke 

     Yio ti se farasin.


5.  E fun ‘pe na kikan 

     Nipa t’ojo isimi

     Ki gbogbo orile-ede 

     Le p’ojo Mimo mo.


6.  E f'Ogo fun Baba

     E f'Ogo fun Omo

     E f'Ogo fun Emi Mimo 

     Metalokan lailai.  Amin

English »

Update Hymn