HYMN 862

15.6.15.6 CM



1.  OLUS’AGUTAN, toju wa,

     Li ojo ibi yi,

     Fun gbogbo omo-ehin Re, 

     N’ ipa lati sona.


2.  B’ igba idanwo wa ba pe, 

     T’ iponju po fun wa,

     Jek‘ emi wa sirni le O,

     L’ adura aisimi.


3.  F’ ore-ofe emi ebe, 

     Fun wa nipa ‘gbagbo; 

     K’a du titi ao r’oju Re, 

     T’ ao si mo oko Re.


4.  Titi O fun wa l’ara Re, 

     Ati ife pipe

     K’eyije igbe gbogbo wa, 

     Nki o je ki O lo.


5.  O ki o lo, bikosepe,

     O s’oko Re fun mi,

     K’ O f’igbala Re bukun mi, 

     Si jeki ndabi Re.


6.  Jeki nr’oju Re kedere

     ‘Gba m’ ba d’ori-oke, 

     Nibit’ a r’ohun t’a gbagbo, 

     T’adura di iyin.  Amin

English »

Update Hymn