HYMN 86

C.M.S 427 H.C. 429. 8s 4 (FE 103)
“Ohun owo Re Ii awa ti fi fun O"
- 1 Kron. 29:14



1.  OLUWA orun on aiye

     Wo n‘iyin at’ope ye fun

     Bawo l‘a ba ti fe O to?

     Onibu‐Ore.


2.  Orun ti nran at’afefe

     Gbogbo eweko nso ‘fe Re;

     ‘Wo l’O nmu irugbin dara,

     Onibu-Ore.


3.  Fun ara lile wa gbogbo

     Fun gbogbo ibukun aiye,

     Awa yin O, a si dupe,

     Onibu-Ore.


4.  O ko du wa li Omo Re,

     O fi fun aiye ese wa,

     O si f’ebun gbogbo pelu;

     Onibu‐Ore.


5.  O fun wa l’Emi Mimo Re,

     Emi iye at’agbara

     O rojo ekun ‘bukun Re,

     Le wa lori.


6.  Fun idariji ese wa,

     Ati fun ireti orun,

     Kil’ohun t’a ba fi fun O?

     Onibu-Ore.


7.  Owo, ti a nna, ofo ni,

     Sugbon eyit’a fi fun O,

     O je isura tit’ aiye

     Onibu-Ore.


8.  Ohun t’a bun O, Oluwa,

     ‘Wo o san le a pade fun wa

     Layo l'a o ta O lore

     Onibu-Ore.


9.  Ni odo Re l’a ti san wa,

     Olorun Olodumare;

     Jek' a le ba O gbe titi

     Onibu-Ore.  Amin

English »

Update Hymn