HYMN 859

CM



1.  OLORUN, ‘ranwo eni Re 

     Reti wa n‘igba bi

     A gba ‘Wo Eni Airi gbo 

     Awa nwa O sibe.


2.  Ese ti awon elese 

     Nfojudi ipa Re

     Ti won si nhale b'enipe 

     ‘Wo ko ri ese won.


3.  Oluwa, dide k'o gba wa 

     A m'oran wa t'O wa

     F‘ododo at'ipa joba

     Wo nikan Ii Oba.


4.  Iwo mo gbogbo ife wa 

     ‘Ranwo Re wa n‘tosi 

     Pese okan wa f'adura 

     Si gba adura wa.  Amin

English »

Update Hymn