HYMN 857

8.8.8 D



1.  MASE beru ‘wo okan mi 

     Eleda mi ni nma foya 

     Oluwa pe mi l’oruko

     O ndabobo, ko si jinna 

     Eje Re ti s‘etu fun mi

     O nfe, O si nto mi sibe.


2.  ‘Gba mo nkoja larin ibu 

     Mo f’igbagbo toro 'ranwo 

     Igbi si duro l’okere

     Won bi kuro Ii ori mi

     Emi ko beru ipa won

     Ko si ewu, Olorun mbe.


3.  Mo yi oju igbagbo s’i 

     Mo ntesiwaju larin ‘na 

     Ina gbagbe lati jo mi 

     Owo ina njo yi mi ka 

     Mo jewo agbar’ami na 

     Mo ke pe" Temi ni Jesu.


4.  Olugbala, duro ti mi 

     Dabobo mi nigba ‘danwo 

     Pa mi mo ni ikawo Re 

     F’agbara ‘gbala han n’nu mi 

     Ki apa Re je abo mi

     Ko s'ohun le ja mi kuro.


5.  B'O si ti pe mi pe ki nwa 

     Wo Olore ti ngba ni la

     Un o rin lori okun ti nja 

     Igbi yo gbe ese mi ro 

     Nki yo beru isan na 

     Bi o ti wu ki o le to.


6.  Gbat‘okunkun b’oju orun 

     T’igbi ‘banuje yi mi ka 

     T‘iji ibinu ru soke

     To fere bori okan mi

     Emi mi yo ri dake je

     Y’o gb‘ohun jeje pe, 'simi.


7.  Bi mo wa n‘nu eru ‘ponju 

     Laisewu un o sete iku

     B’ese doju ija ko mi

     Ti esu gbe ogun ti mi 

     B’igbo Mose, un o ma gberu 

     Ina ki o pa mi lara.  Amin

English »

Update Hymn