HYMN 854

88107



1.  lSEGUN wa li okan mi 

     Nitori Emi ngbe 'nu mi 

     Jeki igbi idanwo de

     Jesu mura lati gba mi.

Egbe: Isegun! Isegun! isegun l‘okan mi

          Mo ni isegun nla ‘tori Jesu 

          gb‘okan mi

          Isegun! lsegun! bi odo sisan 

          Mo nsegun nla ninu eje Jesu.


2.  Bi ‘ja tile le to si pe

     Bi esu tile b‘okan mi ja 

     Sibe, mo je alagbara 

     L’agbara Jesu, ngo segun.

Egbe: Isegun! Isegun!...


3.  Mo ni ‘segun lori ese 

     Mo ni segun lori ‘boji 

     Ani iku ko ni ‘pa mo

     Aleluya! emi ti la.

Egbe: Isegun! Isegun! isegun l‘okan mi

          Mo ni isegun nla ‘tori Jesu 

          gb‘okan mi

          Isegun! lsegun! bi odo sisan 

          Mo nsegun nla ninu eje Jesu.  Amin

English »

Update Hymn