HYMN 851

(FE 893)
Tune: Baba Jo Ranti mi



1.  A dupe lowo Oluwa

    To da wa si d‘oni

    Ti ko f’okan adaba Re 

    Le eranko lowo

    Iku ati Esu gbogun, 

    Sibe ko ta wa nu

    Ogo f'Oba Mimo julo 

    Kabiyesi Oba.


2.  Melomelo lore, Re 

     Oba awon Oba

     Ti pamo ati iso Re, 

     Tabi lsegun ota 

     Loju ala, loju aiye, 

    Tabi ti pese Re 

    Iwosan lona iyanu, 

    A dupe Oluwa.


3.  Owo wa ko to dupe, 

     Aso ko to dupe

     Ko s’ohun ta le fi dupe 

     Bikose ohun wa

     Ka f’okan wa fun Kristi 

     Lati aiye yi lo

     Ka yo orun le je ti wa, 

     Ti Kristi ti seleri.


4.  Bani owo lainiye,

     B’a ni ‘le lainiye

     Ba so wa po bi ti Lilly 

     B'omo po lo titi

     Ba rope ayo wa tikun, 

     Rara ko iti kun

     Oku bako ti seleri 

     Eru ni n‘eru wa.


5.  Kilo tun ba o leru,

     Ti Jesu ko le se

     Damuso lo wa niwaju re, 

     Pe Jesu fun ran ‘wo 

     Peteru pe fun ranlowo, 

     Ko je ko ri somi 

     Hezekiah Oba tun pe,

     O segun Keferi.


6.  Won to feje ti Kristi, 

     Yio pinu lokan won 

     Lati yago fun Lusifa 

     A t'omo ogun re

     Ija, Ibinu, Arakan 

     Ati iwa Eri 

    Ainife ati ailanu, 

    Ko won sile loni.


7.  A dupe lowo Oluwa 

    Oba awon Oba

    Atobiju, Eni ‘yanu 

    Olugbala Eda 

    Eleda, Olojo oni,

    A juba Oko Re

    Ore Re poju kika lo, 

    A dupe Oluwa.  Amin

English »

Update Hymn