HYMN 847

H.C. 401 8.8.8.8.8.8 (FE 888) 
“Nwon simi ninu lala won” - Ifi.14:13



1.  AWON mimo, lala pari 

    Nwon ti ja, nwon si ti segun 

    Nwon ko fe ohun ija mo 

    Nwon da won ‘Ie l’ese Jesu: 

    A! enyin eni ibukun

    Isimi nyin ti daju to!


2.  Awon mimo, irin pari 

    Nwon ko tun sure ije mo, 

    Are at’ isubu d’opin,

    Are on eru ko si mo

    A! enyin eni ibukun 

    Isimi yin ha ti dun to!


3.  Awon mimo, ajo pari 

    Nwon ti gun s’ile ibukun 

    Iji ko deruba won mo 

    Igbi omi ko n’ipa mo

    A! enyin eni ibukun

   E nsimi n’ib’ alafia.


4.  Awon mimo, oku won sun 

    Ninu ile, awon nsona

    Titi nwon yio fi jinde

    Lati fi ayo goke lo

    A! eni ‘bukun, e korin 

    Oluwa at’Oba nyin mbo.


5.  Olorun won, Wo l’ankepe 

     Jesu, bebe fun wa l’oke

     Emi Mimo, Oluto wa 

     F’ore-ofe fun wa d’opin 

     K’a le b’awon mimo simi 

     Ni Paradise pelu Re.  Amin

English »

Update Hymn