HYMN 846

6666
“Ko mi li ona Re, Oluwa” - OD.27:11
Tune: Jesu oro Re ye



1.  ONA Re, Oluwa

     B’o ti wu ko ha to! 

     Fi owo Re to mi 

     Yan ipa mi fun mi.


2.  B’o rorun b’o soro 

     Daradara lo je

     B’o wo, b’o to tara

     Lodo Re l’opin si.


3.  Nko gbodo yan ‘pin mi 

     Nko tile je yan an

     Yan fun mi Olorun

     Ki mba le rin dede.


4.  Ijoba ti mo nwa 

     Tire ni, jek‘ ona 

     T’o re ‘be je Tire 

     Bi beko un o sina.


5.  Gba ago mi, f’ayo

     Tab’ibanuje kun

     B’o ti to l’oju Re

     Yan ‘re tab’ibi mi.


6.  Yiyan ki se temi

     Ninu ohunkohun

     Iwo s’Oluto mi

     Ogbon, ohun gbogbo.  Amin

English »

Update Hymn