HYMN 845

D. 7s 6s (FE 883) 
“Ni bibi emi o mu iru omo re bi si"
- Gen. 16:10
Tune: A Roke A furugbin



1.  OLORUN to fe Abraham 

     To fi se ore re

     Pe ni 'ru omo re laiye

     Yio dabi irawo

     O fi Isaaki seleri

     Lati gba ile na

     O mu ileri na se fun.

     Jakobu omo re.

Egbe: K'a damure lati jagun - 2ce 

          K'a damure e, - 2ce

          K'a damure lati jagun.


2.  Iwo to gbo ti Mosisi 

     Lori oke Sinai

     Iwo to pe Samueli 

     Nigbat‘ o wa lewe 

     Iwo to pelu Dafidi 

     T'o segun Golayat 
  
     E wa di Egbe Serafu

     Lamure ododo.

Egbe: K'a damure...


3.  Gbo ti Jesu Oluwa wa 

     Ti se ileri fun

     Awon Aposteli gbani 

     Lari j‘alagbara

     Nigba nwon gba Emi Mimo 

     Nwon fi ayo sise

     Irapada d'orin fun won

     Titi d’oke orun.

Egbe: K'a damure...


4.  Kerubu ati Serafu 

     E damure giri

     Ki Egbe Aladura 

     Mura lati sise 

     Ileri ti Oluwa se 

     Nipa ti otito

     K’a ranti a o segun

     Ni ojo ikehin.

Egbe: K'a damure...


5.  Enyin eni irapada 

     E korin igbala

     Si eni ti o fe wa 

     To f‘eje Re ra wa 

     Lati oko eru wa 

     Lo si ile Kenaani, 

     Ilu Jerusalemu 

     Lodo Jesu Oba.

Egbe: K'a damure...


6.  Eni to ran Mose lowo 

     Baba Aladura

     Lati se ise Alakoso 

     Serafu, Kerubu

     Fi ‘segun fun de isegun 

     Lati ja ajaye

     Lati gba ade Ogo na 

     B’awon Woli saju.

Egbe: K'a damure lati jagun - 2ce 

          K'a damure e, - 2ce

          K'a damure lati jagun.  Amin

English »

Update Hymn