HYMN 844

C.M.S 478, H.C C.M (FE 881) 
“Nitori ibi hiha Ii enu ona na"
- Matt. 7:14



1.  ONA kan l’o ntoka s’orun 

     Isina ni ‘yoku

     Hiha si l’ojuona na 

     Awon Kristian l’o fe.


2.  Lat’ aiye, o lo tarata 

     O si la ewu lo

     Awon ti nfi igboya rin 

     Y’o d’orun nikehin.


3.  Awon ewe y’o ha ti se 

     Le la ewu yija?

     Tori idekun pe l’ona 

     F’awon odomode.


4.  Gbigboro l‘ona t'opo nrin 

     O si teju pelu

     Mo si mo pe lati dese

     Ni nwon se nrin nibe.


5.  Sugbon k’ese mi ma ba ye 

     Ki nma si sako lo

     Oluwa, jo s’Oluto mi 

     Emi ki o sina.


6.  Nje mo le lo l’aisifoya 

     Ki ngbekel’ oro Re

     Apa Re y‘o s’agutan Re 

     Y‘o si ko won de ‘le.


7.  Beni ngo la ewu yi ja 

     Nipa itoju Re

     Ngo tejumo ‘bode orun 

     Titi ngo fi wole.  Amin

English »

Update Hymn