HYMN 842

C.M.S 459 H.C 469 6s 5s (FE 879)
"Nigbati iwo dubule, iwo ki yio beru"
- Owe 3:24



1.  OJO oni lo tan
 
     Oru sunmole

     Okunkun si de tan 

     Ile si ti su.


2.  Okunkun bo ile 

     Awon ‘rawo yo 

     Eranko at'eiye

     Lo si ‘busun won.


3.  Jesu, f’orun didun 

     F’eni alare

     Jeki ibukun Re 

     Pa oju mi de.


4.  Jek’ omo kekekre

     La ala rere

     S’oloko t‘ewu nwu 

     Ni oju omi.


5.  Ma toju alaisan 

     Ti ko r’orun sun 

     Awon ti nro ibi 

     Jo da won l’ekun.


6.  Ninu gbogbo oru 

     Jek’ Angeli Re 

     Mase oluso mi 

     L’ori eni mi.


7.  Gbat' ile na si mo 

     Jek'emi dide 

     B'omo ti ko l’ese 

     Ni iwaju Re.


8.  Ogo ni fun Baba 

     Ati fun Omo

     Ati f’Emi Mimo 

     Lai ati Iailai.  Amin

English »

Update Hymn