HYMN 84

(FE 101)
"Emi o ma fi ibukun fun Oluwa nigbagbogbo,
iyin Re yio ma wa li eni mi titi" - Ps. 34:1



1.  ENYIN Angeli to wa l‘orun

     E fi iyin fun Baba,

     F‘Egbe to da sile laiye

     Fun igbala emi,

     O ye ki inu wa ko dun

     Ki awa ki o si ma yo!

     Fun iranti lku Jesu

     Lori Agbelebu.

Egbe:  A pa lase I’agbala orun

           Pe k’Egbe yi ma bi si

           A pa lase I'agbala orun

           Pe O si ma re si;

           Titi gbogbo ifoju okan

           Yio fi tan laiye

           T’iku Jesu Oluwa wa,

           Ko ni je asan mo.


2.  Kerubu ati Serafu

     E fi iyin fun Baba

     Ti o da Egbe yi sile,

     Pe k’a le ri igbala,

     “Torina, e je k‘a mura

     Lati sare ije yi,

     Bi a ba foriti d’opin

     lye y’o je ti wa.

Egbe:  A pa lase...


3.  Gbogbo ise wa ti a nse,

     Gbogbo iwa ti a nhu,

     Gbogbo oro wa ti a nso,

     E je k‘a ma sora;

     Nitori Oluwa yio mu,

     Gbogbo ‘se wa si ‘dajo

     Ati gbogbo ohun ‘koko

     Ire tabi ibi.

Egbe:  A pa lase...


4.  Awa ni imole aiye

     Lati le okunkun lo,

     llu ta te sori oke

     A ko le fara sin;

     Awa si ni iyo aiye

     Ti a o mu aiye dun

     Sugbon b’iyo ba di obu,

     Bawo ni yio se dun?

Egbe:  A pa lase...


5.  Ope lo ye Olugbala,

     Fun ife to ni si wa,

     Ti o pe wa si Egbe yi,

     Oko ‘gbala ‘kehin

     Ogo, ola at’agbara

     Ola nla at‘ipa

     Ni fun Baba, Omo, Emi

     Metalokan lailai.

Egbe:  A pa lase...  Amin

English »

Update Hymn