HYMN 839

(FE 876)
Tune: C.M.S 303 10s



1.  OJU ko ti ri, eti ko ti gbo

     Ese t‘OlugbaIa pa f’enia Re 

     Awon ti O feran ti nwon feran Re 

     Ti nwon nfi ayo sin ninu ile Re.


2.  B‘Orun ti dun to ko si‘eni le mo 

     Ayo re ko ti la s'okan eda

     Bi ijoba aiye ba lewa to yi 

     Bawo n’ijoba Olorun yio ti ri?


3.  Ilu ail'ese ti ko si iku 

     Nibiti a ki pe ‘O digbose

     Ti ko si ipinya ti ko si ekun 

     Ibiti Jesu joba yio ti layo to.


4.  lpade pelu awon to ti lo

     Baba t‘on t'omo oko t‘on t‘aya 

     Ore at’ojulumo t’o ti saju

     A! b’ijoba Olorun yio ti dun to.


5.  Pelu awon mimo lati ma ko

     Orin Mose ati t‘Od-agutan

     Nibiti ko si aniyan fun ara

     Ti jesu gbe nsike wa yio ti dun to.


6.  Ki npadanu aiye on oro re

     K‘ese mi le te ilu ogo yi

     Nigba mo ba nrin ita wura l'oke 

     Ngo gbagbe gbogbo iya ti mo ti je.  Amin

English »

Update Hymn