HYMN 837

C.M.S 465 H.C 503 7s (FE 974)
“O gbe owo Re le won O si sure 
fun won" - Marku 10:16



1.  JESU fe mi, mo mo be 

     Bibeli l‘o so fun mi

     Tire l‘awon omode 

     Nwon ko lagbara, On ni.


2.  Jesu fe mi En’to ku 

     Lati si orun sile 

     Yio we ese mi nu 

     Jeki omo Re wole.


3.  Jesu fe mi sibe si

     Bi emi tile s‘aisan 

     Lor'akete aisan ni 

     Y’o t‘ite Re wa so mi.


4.  Jesu fe mi, y’o duro

     Ti mi ni gbogb’ona mi

     Gba mba f’aiye yi sile 

     Y’o mu mi re ‘le orun.  Amin

English »

Update Hymn