HYMN 835

T. c.m.s 385 c.c. 25 p.m (FE 872)
Ohun: Gbekele Olurun Re
“Oluwa ni mo gbeke mi le” - Ps. 11:1



1.  GBOGBO Egbe Serafu 

     Foriti, e foriti 

     Ma je k’o re gbogbo nyin 

     E foriti

     Ninu irin-ajo re 

     Efufu lile le ja

     Ja fun ‘se re ma beru 

     Sa foriti.


2.  Kerubu pelu Seraf 

     Foriti, e foriti 

     Awon Woli isaju 

     Nwon foriti

     Mura si ‘se ma w’ehin 

     Baba y'o gb'adura re 

     E foriti iponju

     Sa foriti.


3.  Egun le wa lona 

     Foriti, e foriti

     W'o oke sile ‘bukun ni 

     E foriti

     Ranti oro to nwipe 

     E o fi iye goke 

     Lagbara Metalokan

     A ogb’ade.  Amin

English »

Update Hymn