HYMN 832

8s 7s (FE 869)
“E f’ope fun Oluwa" - Ps. 136:1
Tune: Jesu Mo Gbagbelehu Mi



1.  A DUPE lowo Jehovah 

    Oba Onibu-ore 

    Fun isegun t’o se fun wa 

    Larin odun t’o koja. 

Egbe: Awa si njo, awa si nyo 

          Fun idasi wa oni

          Ayo kun okan wa loni 

          Ogo fun metalokan.


2.  Ojo ayo l’oni fun wa 

     Awa si nse ‘sin oro 

     Kerubu ati Serafu 

     E jeki a jo yin Baba.

Egbe: Awa si njo...


3.  Jesu Olori Egbe wa 

     jek’ a ri O l’arin wa 

     Awa f’iyin fun O loni 

     Fun idasi erni wa.

Egbe: Awa si njo...


4.  Kerubu ati Serafu

     Awa l’ayanfe Omo 

     Fun Olorun Metalokan 

     Oba Awimayehun.

Egbe: Awa si njo...


5.  Gbogbo aje t’o wa laiye 

     Agbara won ti wo mi 

    Ni agbara Metalokan 

    Awa y’o segun esu.

Egbe: Awa si njo...


6.  Ojo aye wa nlo s‘opin 

     E jek‘a mura s'ise 

     Gbogbo ise t'awa yio se 

     Okan ki yio lo lasan.

Egbe: Awa si njo...


7.  A ki baba Aladura 

     K‘Olorun ko bukun o 

     Ade Ogo y‘o je tire 

     L'Agbara Metalokan.

Egbe: Awa si njo, awa si nyo 

          Fun idasi wa oni

          Ayo kun okan wa loni 

          Ogo fun metalokan.  Amin

English »

Update Hymn