HYMN 830

H.C. 492 7.6.8.6 (FE 867)
“Ko eko ti emi, nitori oninu tite ati 
oninu tutu Ii emi" - Matt. 11:29



1.  MO fe ki ndabi Jesu 

     Ninu iwa pele

     Ko s’enit‘o gboro binu 

     Lenu Re lekan ri.


2.  Mo fe ki ndabi Jesu 

     L’adura ‘gbagbogbo 

     L’ori oke ni On nikan 

     Lo pade Baba Re.


3.  Mo fe ki ndabi Jesu 

     Emi ko ri ka pe

     Bi nwon ti korira Re to 

     O s’enikan n’ibi.


4.  Mo fe ki ndabi Jesu 

     Ninu ise rere
   
     K’a le wi nipa temi pe 

     O se ‘won t’o le se.


5.  Mo fe ki ndabi Jesu 

     T’o f’iyonu wipe

     Jeki omode wa sodo Mi 

     Mo fe je ipe Re.


6.  Sugbon nko dabi Jesu

     O si han gbangba be 

     Jesu fun mi l’ore-ofe 

     Se mi ki ndabi Re.  Amin

English »

Update Hymn