HYMN 827

t.H.C 6s 8s (FE 864)
“Oluwa si wi fun Mose pe, Emi li
eniti o wa" - Eks. 3:14 
Tune: E fun ‘pe na kikan



1.  MOSE Orimolade 

     Ni Oluko wa, 

     Olorun ran s'aiye 

     Lati d'egbe yi sile.

Egbe: Kerubu, Serafu l’o so)

          Oruko Egbe na.) -2ce


2.  Olorun Tunolase 

     Ran Emi re si wa, 

     Ka mase se aseti 

     Ninu adura wa.

Egbe: Metalokan jo gbo tiwa)
  
           Fun wa n'ida Emi) - 2ce


3.  Ma je k'esu tan wa,

     Lati se Tunolase

     Ka ma d'eni egbe

     Ni ojo ikehin.

Egbe: Metalokan jo gbo tiwa)

          Fun wa n'ida Emi) - 2ce


4.  Lonakona t’ota,

     Ba ngbogun re si wa; 

     Baba Olusegun, 

     Segun logan fun wa.

Egbe: Oluwa Olorun omo gun) 

           Ma jek’ oju ti wa) - 2ce


5.  Gbogbo eyin te duro 

     Lati je omo Mose 

     Olupilese IYE

     Yio di nyin mu dopin.

Egbe: Om'Alade Alafia)

           F'alafia fun wa.) - 2ce


6.  A nlo si ile wa, 

     F‘ogun orun yi wa ka 

     Ki gbogbo ibi aiye 

     Ma le se wa nibi.

Egeb: P‘Aje, Oso Sonponna run) 

           F'awa omo Jesu) - 2ce


7.  Baba Aladura

     Ti Baba gbe dide 

     K‘Olorun ran lowo 

     Ko gbowo re soke.

Egbe: Edumare, jo gbo tire) 

          B'o ti gbo ti Mose) - 2ce.  Amin
 

English »

Update Hymn